1. BI agbonrin ti nmi hele,
S’ ipa odo omi;
Beni okan mi nmi si O,
Iwo Olorun mi.
2. Orungbe Re ngbe okan mi,
Olorun Alaye;
Nigbawo ni ngo r’ oju Re,
Olorun, Olanla?
3. Okan mi, o se rewesi?
Gbekele Olorun,
Eniti yio so ekun re,
D’ orin ayo fun o.
Stanza 4 of Hymn 274
Yioti pe to, Olorun mi,
Ti ngo d’ eni ‘gbagbe?
T’ao ma ti mi sihin sohun,
B’ eni ko n’ ibugbe.
Stanza 5 of Hymn 274
Okan mi, o se rewesi?
Gbagbo, ‘wo o si ko
Orin iyin s’ Olorun re,
Orisusn emi re.
(Visited 1,504 times, 2 visits today)