YBH 276

WA, iwo isun ibukun

1. WA, iwo isun ibukun,
Je ki nkorin ore Re:
Odo anu ti nsan titi,
Bere orin ‘yin kikan;
Oluwa, ko mi l’ orun na
T’ ogun orun nko l’ oke;
Je ki nrohin isura na
Ti ife Olorun mi.

2. Nihin l’a ran mi lowo de,
Mo gbe Ebenesar ro;
Mo nreti nipa anu Re,
Ki nde ‘le l’ alafia;
L’ elejo ni Jesu wa mi,
‘Gba mo sako lo l’ agbo;
Lati yo mi ninu egbe,
O f’ eje Re s’ etutu.

3. Nit’ or-ofe, lojojumo
Ni ‘gbese mi si npo si;
K’ ore-ofe yi ja ewon
Ti nse ‘dena okan mi;
Ki nsako lo l’ okan mi fe,
Ki nk’ Olorun ti mo fe:
Olugbala, gba aiya mi,
Mu ye f’ agbala orun.

(Visited 1,040 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you