1. GBAT, a b’Oluwa rin
N’nu ‘mole oro Re
Ona wa yi o ti l’ogo to!
‘Gbat’ a ba nse f’e Re
On y’o ma ba wa-gbe
Ati awon t’o gbeke won le.
Sa gbekele
Ona miran ko si
Lati l’ayo n’nu Jesu,
Afi k’a gbekele.
2. Ko si ajaga mo
Ko si ‘banuje mo
Gbogbo wahala wa ti pari
Ko si arokan mo,
Tabi ifajuro,
Afi ‘bukun, t’a ba gbekele
3. Awamaridi ni
Ayo ife nla Re
Titi ao fi f’ara wa rubo,
Anu ti O nfi han,
At’ ayo t’O nfun ni
Je ti awon ti o gbekele
4. Ni idapo didun
L’ao joko l’ese Re
Tabi ki a ma rin pelu Re,
Awa y’o gbo ti Re,
Ao jise to ran wa,
Mase beru sa gbeke re le
(Visited 9,848 times, 7 visits today)