YBH 279

AYO awon ti to

1. AYO awon ti to,
T’ o gb’ Olugbala gbo,
T’o to isura nwon si oke
Ahon ko le s’ adun
Itunu alafia,
Ti okan l’ akobere ife.

2. O ti je t’ emi ri,
Nigba mo ri ore,
Nipa eje Odo-agutan;
A, ayo ti mo ri,
Nigba mo ko gbagbo!
Ayo l’ oruko Jesu didun.

3. Mimo Olugbala
So ‘le aiye d’ orun:
Awon Angeli ko le se ju,
Lati wole fun U;
Ki nwon tun ‘tan na so
Ki nwon bo Olufe elese.

4. Jesu ni orin mi
Ni wakati gbogbo;
Gbogb’ aiye ‘ba le r’ igbala Re;
Mo nke pe, “O fe mi,
P’ O jiya, O si ku,”
Lati gba ota bi emi la.

5. B’ ayo mi ti ga to!
Ayo ni ti mo ri
Ninu eje tin fun ni n’ iye!
Pel’ Olugbala mi:
Mo l’ ekun ibukun,
B’ enipe mo kun fun Olorun.

(Visited 181 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you