1. BENI, O bikita fun mi,
Pelu ike bi t’ egbon ;
Beni, eru at’ ifoiya,
Gbogbo re l’ O mba mi pin.
2. Beni, fun mi li O mbebe,
Ni ite-anu loke;
Nigbagbogbo l’O mbe fun mi,
Pelu ‘fe ti ko l’ are.
3. O ntan ayo t’ o ju t’ aiye,
Lat’ okere sinu mi,
Lati bo mi, O tai ye
Ipa Re bi ti baba.
4. Beni, O ngbe ‘nu okan mi,
Emi si ngbe inu Re;
O si kun okan ofo mi,
L’ aiye yi ati lailai.
5. Mo si nduro de bibo Re,
Pel’ orin lona orun;
Be l’ orin ayo owuro,
Be ni orin asale.
(Visited 238 times, 1 visits today)