YBH 281

JESU o ye ki nl’ ayo

1. JESU o ye ki nl’ ayo,
Ti mba le gbekele O,
Pe ogbon Re to to mi,
Pe ore Re to pese,
Pe ipa Re to gbala,
Ki now O nigbagbogbo.

2. Ki nwo O, ‘Mole kanso,
Nigba ale ba sokun,
Ninu sisan, n’ ilera,
Ninu oro on osi,
N’ ibanuje at’ ayo,
Wo ‘leri Re fun ‘ranwo.

3. W’ eje Re fun ‘wenumo,
W’ ore Re fun ilera,
Wo o n’ iye at’ iku,
Ki nma wo O l’ ona mi;
Tit’ ao fi gbin ese mi
Sinu okun didan ni.

(Visited 427 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you