1. BI Jesu ba fe mi,
Bi mo ba je Tire,
Nko ko ohun t’ ota le ro,
Bi nwon tile n’ ipa.
2. Mo simi le ori
Jesu, on eje Re;
‘Tori ninu Re nikan ni
Mo ri oto ire.
3. Okan mi fo l’ ayo,
Ko le banuje mo,
O nfi erin ko ‘rin ayo,
O nri ‘mole ayo.
4. Orun to la ‘ju mi,
Ni Kristi ti mo fe,
Mo fi ayo ko ‘rin oro
Ti a pese fun mi.
(Visited 324 times, 1 visits today)