YBH 284

OKAN mi nsimi, Oluwa

1. OKAN mi nsimi, Oluwa;
Ngo dupe, ngo ko ‘rin,
Okan mi r’ ibi asiri
Ti ire ti nsun wa.

2. Mo k’ ongbe orison iye,
O se yo l’ ara Re;
Mo wa isura ife Re,
O si wa nitosi.

3. Oro orin de enu mi,
T’ a f’ ohun didun si;
Ogo ni fun O fun ore,
T’ emi ko ti towo.

4. Mo ni ogun ayo l’ oke
Ti nko ti f’ oju ri;
Sugbon eje t’ o pese re,
Li O npamo fun mi.

5. Okan mi nsimi, Oluwa,
O wa ni ike Re;
B’ o ba ti nr’ ayo ninu Re,
Yio le gbekele O.

(Visited 393 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you