1. ENYIN t’ e fe Oluwa,
E fi ayo nyin han,
E jumo ko orin didun,
E jumo ko orin didun,
K’ e si y’ ite na ka,
K’ e si y’ ite na ka.
A nyan lo si Sion,
Sion t’ o darajulo,
A nyan g’ oke lo si Sion,
Ilu Olorun wa.
2. Jek’ awon ni ma ko
Ti ko m’ Olorun wa
Sugbon awa omo Oba,
Yio so ayo won ka.
3. Oke Sion nmu
Egberun adun wa;
Ki a to de gbanga orun,
Pelu ita wura.
4. Nje k’ a ma korin lo,
K’ omije gbogbo gbe,
A nyan n’ ile Emanuel
S’ aiye didan l’ oke.
(Visited 6,131 times, 41 visits today)