1. MO gbohun Jesu t’ o wipe,
“Wa simi lodo Mi;
Gbe ori re, ‘wo alare,
Le okan aiya Mi.”
Ninu are on ‘banuje,
Ni mo to Jesu wa;
O je ib’ isimi fun mi,
O si mu ‘nu mi dun.
2. Mo gbohun Jesu t’ o wipe
“Iwo ti ongbe ngbe,
Ngo f’ omi ‘ye fun o lofe,
Bere, mu k’ o si ye.”
Mo to Jesu wa, mo si mu
Ninu omi ‘ye na;
Okan mi tutu, o soji,
Mo d’ eni alaye.
3. Mo gbohun Jesu t’ o wipe,
” ‘Mole aiye l’ emi;
Wo Mi, Emi ni Orun re,
Ojo re yio dara.”
Mo wo Jesu, emi si ri
B’ Orun ododo mi,
Ninu ‘mole yi l’ emi o rin
Tit’ ajo mi yio pin.
(Visited 1,065 times, 1 visits today)