1. JESU, kiki ironu Re,
Fi ayo kun okan;
Sugbon k’ a ri O l’ o dun ju,
K’ a simi lodo Re.
2. Enu koso, eti ko gbo,
Ko ti okan wa ri;
Oko t’ o sowon, t’ o dun bi
Ti Jesu Oluwa.
3. Ireti okan ti nkanu,
Olore elese;
O seun f’ awon ti nwa O,
Awon t’ o ri O yo.
4. Ayo won, enu ko le so,
Eda ko le rohin;
Ife Jesu b’ o tip o to
Awon Tire l’ o mo.
6. Jesu, ‘Wo ma je ayo wa,
‘Wo sa ni ere wa;
Ma je ogo wa ni sinyi
Ati titi lailai.
(Visited 462 times, 1 visits today)