1. JI, okan mi dide l’ ayo,
Korin iyin Olugbala;
Ola Re bere orin mi,
‘Seun ife Re ti po to!
2. O ri mo segbe n’ isubu,
Sibe o fe mi l’ afetan;
O yo mi ninu osi fun.
‘Seun ife Re ti po to!
3. Ogun ota dide si mi,
Aiye at’ Esu ndena mi,
On mu mi la gbogbo re ja;
‘Seun ife Re ti po to!
4. ‘Gba ‘yonu de, b’ awosanma
T’ o su dudu t’ o nsan ara;
O duro ti mi larin re
‘Seun ife Re ti po to!
5. ‘Gbagbogbo l’ okan ese mi
Nfe ya lehin Oluwa mi;
Sugbon bi mo ti ngbagbe Re
Iseun ife Re ki ye.
6. Mo fere f’ aiye sile na
Mo fe bo low’ ara iku,
A! k’ emi ikehin mi ko
Iseun ife Re ki ye.
7. Nje ki nfo lo, ki nsi goke
S’ aiye imole titi lai,
Ki nf’ ayo iyanu korin
Iseun ife Re ki ye.
(Visited 2,296 times, 1 visits today)