1. A! mba le l’ egberun ahon.
Fun ‘yin Olugbala,
Ogo Olorun Oba mi,
Isegun ore Re.
2. Jesu t’ O s’ eru wa d’ ayo,
T’ O mu ‘banuje tan;
Orin ni l’ eti elese,
Iye at’ ilera.
3. O segun agbara ese
O da ara tubu;
Eje Re le w’ eleri mo,
Eje Re se fun mi.
4. Baba mi at’ Olorun mi,
Fun mi n’ iranwo Re;
Ki nle ro ka gbogbo aiye,
Ola oruko Re.
(Visited 4,862 times, 1 visits today)