1. IRO t’ o dun ju orin,
Fa mi l’ oruko Jesu,
Gbogbo ‘reti okan mi
Wa lor’ agbelebu Re.
2. Gbat’ o de, angel ko ‘rin
Ogo s’ Olorun l’ oke;
Tu ahon mi, Oluwa,
Tani ba ko ju mi lo?
3. Oluwa ha d’ enia,
K’ O ba le mu ofin se?
O ha jiya n’ ipo mi,
Ki ahon mi dake bi?
4. Beko, ngo mu iyin wa,
Bi ko tile nilari,
Ti mba ko lati ko ‘rin,
Daju okuta yio dun.
5. Olgbala, Asa mi,
Oluso at’ Ore mi,
Oruko owon l’ okan,
Ngo fe O titi lailai.
(Visited 254 times, 1 visits today)