1. IFE t’ o rekoja ero,
T’ o se ‘lana rere,
Fun ‘gbala enia, ki Adam
T’ o mu isubu wa.
2. Olorun fe iran wa be,
T’ o f’ Omo Re toro,
Pe, enit’ o fe le wo O,
Ko r’ iye l’ ara Re.
3. ‘Bukun ni fun Baba, lodo
Enit’ ire ti nsan;
‘Bukun ni fun OMO, Oba
At’ Olugbala wa.
4. A mo, a si gba ‘fe na gbo,
T’ o t’ ipa Jesu han;
‘Gba ba ri oju Re loke,
Ao le orin titun.
(Visited 536 times, 1 visits today)