YBH 3

EYO gbogb’ orile-ede

1. EYO gbogb’ orile-ede
N’ iwaju Ob’ Alade yin,
E sin pelu inudidun,
Fi gbogbo ahon yin l’ ogo.

2. Oluwa On ni Olorun,
T’ O fun wa ni gbogbo ebun;
Ise owo Re l’ awa se,
Agutan inu papa Re.

3. E f’ orun ayo s’ ilekun,
E f’ iyin wo agbala Re,
E si se n’ ise t’ o l’ ogo,
Lati f’ ope at’ ola fun.

4. Olore at’ Alanu ni,
Ebun at’ anu Re daju,
Gbogbo oril’-ede y’o mo
Pe otito Re wa lailai

(Visited 596 times, 3 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you