1. OWO at’ Alabukunfun
Ni ile t’ o jewo Jesu,
Okan at’ ile na l’ ayo
Nibiti Olugbala wo.
2. Gb’ ori s’ oke, ilekun nla,
E wo, Oba ogo duro:
Oba awon oba mbowa,
Olugbala araiye de.
3. E si ‘lekun okan paya,
Bi tempili t’ a ya soto
Fun elo ohun ti orun,
Ti a fi ife se l’ oso.
4. Wa Olugbala, mo ti si
Okan paya, ma gbe ‘nu mi,
T’ ayo, t’ ope ni ngo ko’ rin,
Ngo f’ igbe aiye mi yin O.
(Visited 364 times, 1 visits today)