1. IMOLE ojo ‘simi
Je l’ o ku mo wa l’ oju,
B’ igbat’ orun iba wo,
Fun ajo onigbagbo.
2. B’ imole ti nrekoja,
Oru t’ as obo aiye;
Gbogbo nkan dake roro,
N’ ipari ojo ‘simi.
3. Alafia kun aiye;
Ti Olorun mimo ni, –
Apere t’ inu okan
Ti o bo lowo ese.
4. Sibe Emi duro ti
Awon t’ o nsin l’ asale,
T’ o gbe okan nwon s’oke,
T’ o nsare si ebun na.
5. Jesu je k’ isimi wa
Je ti ayo ninu Re,
Tit’ okan wa y’o simi,
Nibi ‘simi ailopin.
(Visited 285 times, 1 visits today)