1. BABA, aniyan at’ eru
Le su l’ ojo ola,
Sugbon ‘foya ko le wo ‘bi;
Tire l’ ojo oni.
2. A k’y’o da okan si meji
Lati sin n’ ile Re;
Ki ero aimo k’ o fo lo,
K’ ile si je Tire.
3. Sun l’ oni, aniyan okan,
Fun ohun ti aiye;
E ki y’o di oju ‘mole
T’ o ntan l’ oro oni.
4. Aye mbe li ojo ola
Lati sa ipa nyin;
E k’yo ba ojo oni je,
Ojo ‘simi t’ okan.
(Visited 297 times, 1 visits today)