1. OLUWA, isimi Re dun;
Sugbon t’ oke ju ti aiye lo;
Sibe pelu ‘reti ayo
Li okan ongbe wa nsare.
2. Ko si are, ko si ise,
Ese, iku ki y’o de ‘be
Ohun irora ki y’o dun,
Nibiti ahon aiku wa.
3. Ko si idagiri ota;
Isimi laisi aniyan;
Oju ojo ko su nibe,
Osangangan aiyeraiye.
4. Bere, ojo t’ a ti nreti,
Mo si aiye irora yi,
Ao f’ ayo rin l’ ona t’ a yan,
Ao si sun ninu Oluwa.
(Visited 342 times, 1 visits today)