1. GBOGB’ ogun orun nro keke,
Angeli mu harpu won,
Awon mimo nt’ ohun won se
Lati josin t’ o l’ ogo;
Ojo ‘simi t’ Olorun de,
Ojo t’ o l’ ogo julo,
Orun kun fun iho ayo,
A! b’ isin won ti dun to.
2. Jek’ a pelu awon t’ orun
Yin Olorun Oba wa;
Jek’ a pa ‘le okan wa mo,
K’ a f’ ohun mimo korin;
Apere ni ti wa le je
T’ isimi tin won loke,
Tit’ ao fi ri Oluwa
Ti a nsin l’ ojukoju.
3. K’ o to d’ igba na, e jeki
A ma sin l’ ojo keje,
K’ a f’ aniyan wa s’ apakan,
K’ a pe sinu ile Re;
O ti pase k’ a ma se be,
Y’o bukun ipejo wa,
E jek’ a sin li aisare,
Ere re y’o je tiwa.
(Visited 660 times, 1 visits today)