YBH 34

EMI wa ba w ape

1. EMI wa ba w ape,
L’ ojo isimi yi;
Laisi Re awa ko le sin,
A ko le gb’ adura.

2. Asan li orin wa,
Iwasu wa asan,
Ipejopo wa ko l’ ere
Afi b’ O pelu wa.

3. Ojise Orun nla,
Tani mo je bi Re?
Tikalare wasu fun wa
Nipa iranse Re.

4. Wa ko wa lati be,
L’ ohun t’ a ba toro;
Si mu ‘bere wa to Jesu
T’ a be l’oruko Re.

5. Nipa ‘ranlowo Re
L’a n’ ireti anu,
Isin wa ko le sai l’ ere
B’ Iwo ba pelu wa.

(Visited 1,143 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you