1. LODO Re sibe nigbat’ ojumo mo,
Ti awon eiye ji, ti kuku lo:
Rekoja t’ orun ni didan imole,
Idaloju pe, “O wa lodo mi.”
2. Nigbati are mu okan mi togbe,
O ko ‘ju si O ninu adura;
Orun na ti dun to labe iji Re,
Sugbon k’ a ji k’ a ri O dun julo.
3. Beni, yio ri l’ owuro ikehin ni,
Ti okan ji, ti kuku aiye lo;
Gbana ninu ewa t’ o ta t’ orun yo,
Ero, “mo wa pelu re” yio soji.
(Visited 223 times, 1 visits today)