1. JE, Oluwa, sin wa jeje,
L’ aiye omije yi ja,
Si fun wa l’ ore-ofe Re
Ninu eru wa gbogbo:
Tu wa ninu
Larin aginju aiye.
2. Gba ‘damu nta ‘fa yi wa ka,
Ti a fonka kariri;
Mase je ki ore Re ye;
Sin wa l’ ona pipe Re.
3. L’ akoko opo irora,
Nigba ‘ku sunmo ‘tosi,
Masa je ki are mu wa,
Ma jek’ okan wa beru;
4. Nigbati aiye wa pari,
Jek’ a simi l’ apa Re,
Tit’ awon de Angeli y’o fi
Gbe wa de ‘bi ibukun:
(Visited 339 times, 1 visits today)