1. NGO sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O;
B’ o tile se ‘ponju,
L’ o mu mi wa;
Sibe orin mi je,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O,
2. Ni ona ajo mi,
B’ ile ba su,
Bi okuta si je
Irori mi;
Sibe nin’ ala mi,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O.
3. Nibe jeki nr’ ona
T’ o lo s’ orun,
Gbogb’ ohun t’ O fun mi,
Nin’ anu ni,
Angel’ lati pe mi,
Sunm’ O, Olorun mi,
Ngo sunmo O.
4. Nje ‘gbati mo ba ji,
Em’ o yin O:
Ngo f’ akete mi se
Betel fun O.
Be ninu osi mi,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O.
5. ‘Gba mba fi ayo lo
S’ oke orun,
T’ o ga ju orun lo,
S’oke giga.
Sibe orin mi je,
Ngo sunm’ O, Olorun,
Ngo sunmo O.
(Visited 3,547 times, 14 visits today)