YBH 310

OLORUN lat’ oro d’ ale

1. OLORUN lat’ oro d’ ale,
Wakati wo l’ o dun pupo,
B’ eyi t’ o pe mi wa ‘do Re
Fun adua?

2. Ibukun n’ itura oro;
Ibukun si l’ oju ale;
Gbati mo f’ adua goke
Kuro l’ aiye!

3. ‘Gbana ‘mole kan mo si mi,
O dan ju ‘mole orun lo;
Iri ‘bukun t’ aiye ko mo
T’ odo Re wa.

4. Gbana l’ agbara mi d’ otun,
Gbana l’a f’ese mi ji mi,
Gbana l’ of f’ ireti orun
M’ ara mi ya.

5. Enu ko le so ibukun
Ti mo nri f’ aini mi gbogbo;
Agbara, itunu, ati
Alafia.

6. Eru at’ iyemeji tan
Okan mi f’ orun se ile:
Omije ‘ronupiwada
L’ a nu kuro.

7. Titi ngo de ‘le ‘bukun na
Ko s’ anfani t’ o le dun bi
Ki nma tu okan mi fun O
Nin’ adua.

(Visited 492 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you