1. WA k’ a da m’ awon ore wa
Ti nwon ti jere na;
N’ ife k’ a f’ okan ba won lo
S’ ode orun lohun.
2. K’ awon t’ aiye d’ orin won mo,
T’ awon t’ o lo s’ ogo;
Awa l’ aiye, awon l’ orun,
Okan ni gbogbo wa.
3. Idile kan n’nu Krist’ ni wa,
Ajo kan l’a si je;
Isan omi kan l’o yaw a,
Isan omi iku.
4. Egbe ogun kan t’Olorun
Ase Re l’a sin se;
Apakan ti wo ‘do na ja,
Apakan nwo lowo!
5. Emi wa fere dapo na,
Y’o gb’ade bi ti won;
Ao yo s’ami Balogun wa,
Lati gbo ipe Re.
6. Jesu, so wa, s’amona wa,
Gbat’oniko ba de;
Oluwo, pin omi meji,
Mu wa gunle l’ayo.
(Visited 450 times, 1 visits today)