1. ADUA didun adua didun,
T’o gbe mi lo kuro l’aiye,
Lo ‘waju ite Baba mi,
Ki nso gbogbo edun mi fun;
Nigba ‘banuje at ‘aro
Adua l’abo fun okan mi:
Emi sib o lowo Esu
Gbati mo ba gb’adua didun.
2. Adua didun adua didun;
Iye re y’o gbe ebe mi,
Lo sod’emit’o seleri;
Lati bukun okan adua,
B’O ti ko mi ki nwoju Re,
Ki ngbekele ki nsi gbagbo
Ngo ko gbogb’aniyan mi le E,
Ni akoko adua didun.
3. Adua didun adua didun;
Je ki nma r’itunu re gba,
Titi ngo fi d’oke Pisgah;
Ti ngo r’ile mi l’okere
Ngo bo ago ara sile
Lati jogun ainipekun:
Ngo korin bi mo t info lo,
Odigbose Adua didun.
(Visited 4,753 times, 4 visits today)