YBH 314

IGBAGBO mi nwo O

1. IGBAGBO mi nwo O,
Iwo Od’-agutan,
Olugbala
Jo gbo adua mi,
M’ese mi gbogbo lo,
K’emi lat’oni lo
Si je Tire.

2. Ki ore-ofe Re
F’ ilera f’ okan mi,
Mu mi tara:
B’ Iwo ti ku fun mi,
A! k’ ife mi si O,
K’ o ma gbona titi,
Ina iye

3. ‘Gba mo rin l’ okunkun,
T’ ibinu yi mi ka,
S’ amona mi,
M’ okunkun lo loni,
N’ omije anu nu,
Lai, ma je ki nsako
Li odo Re.

4. Gbati aiye ba pin,
T’ odo tutu iku,
Nsan lori mi;
Jesu, ninu ife,
Mu k’ ifoiya mi lo,
Gbe mi d’ oke orun
B’ okan t’ a ra.

(Visited 12,804 times, 13 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you