1. B’ AYO aiye ti j’ asan to!
Didara won ko pe!
Ko s’ ayo ti ko l’ ororo,
Adun re je ‘dekun.
2. Gbogb’ ohun t’ o dara l’ aiye,
Li o nfi etan dan,
O ye k’ a fura nigb’ ayo,
Pe, ewu sunmo ni.
3. Ayo wa, at’ awon t’ a fe,
At’ awon ebi wa,
Nwon ko jek’ a le f’ okan wa
Gbogbo fun Olorun.
4. Ife si ohun ti aiye
Ti gba wa l’ okan tan,
O soro lati mu ‘tara
Wa kuro ninu re.
5. Olugbala, ki ewa Re
Je onje f’ okan mi;
K’ ore-ofe wi f’ okan mi,
K’ o ju aiye sile.
(Visited 388 times, 1 visits today)