1. JESU, agbara mi,
Iwo l’ aniyan mi,
Emi fi igbagbo w’ oke,
Iwo l’ O ngb’adua.
Jeki nduro O,
Ki nle se ife Re,
Ki Iwo Olodumare
K’o so mi di otun.
2. Fun mi l’ okan ‘rele,
Ti ‘ma se ara re;
Ti ntemole, ti ko nani
Ikekun Satani:
Okan t’ ara re mo
Irora at’ ise;
T’ o nfi suru at’ igboya
Ru agbelebu re.
3. Fun mi l’ eru orun,
Oju t’ o mu hanhan,
T’y’o wo O n’gb’ ese sunmole,
K’ o ri b’ Esu ti nsa.
Fun mi ni emi ni,
T’ O ti pese tele.
Emi t’ o duro gangan lai
T’ o nf’ adura s’ ona.
4. Mo gbekel’ oro Re
‘Wo l’ o leri fun mi;
Iranwo at’ igbala mi
Y’o t’ odo Re wa se,
Sa je kin le duro,
K’ ireti mi ma ye,
Tit’ Iwo o fi m’ okan mi
Wo ‘nu isimi Re.
(Visited 3,825 times, 2 visits today)