YBH 319

B’ENU mi dun bi t’ awon ju

1. B’ENU mi dun bi t’ awon ju,
T’ ede mi ta t’ angeli yo;
Laisi ife mo dab’ ide,
Ti ohun re nhan ni l’ eti.

2. Bi mo le f’ ogbon mi wasu
Gbogbo nkan tin won nse l’ orun;
B’ igbagbo mi le s’ oke n’di,
Lais ife, asan ni mo je.

3. Bi mo pin gbogbo ii mi,
Lati fi b’ awon alaini,
Ti mo f’ ara mi fun sisun,
Lati gb’ ogo awon martir’:

4. Bi nko f’ eda at’ Olorun,
Gbogbo ‘reti mi je lasan,
Gbogbo ebun t’ o wu k’ a ni,
Ko s’ eyit’ o dabi ife.

(Visited 453 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you