1. ARA e jek’ a jumo rin
N’ ife on alafia;
A ha le ma tun bere pe,
O to k’ a ba f’ ija mo?
Ni irepo
L’ ayo, ife y’o fi po.
2. B’ a ti nrin lo s’ ile, jek’ a
Ran ‘ra wa lowo l’ ona;
Ota ka wa nibi gbogbo,
S’ ona gbogbo l’ a dekun,
Ise wa ni
K’ a ma ran ‘ra wa l’ eru.
3. Nigbat’ a r’ ohun Baba se,
T’ O ti fi ji, t’ O nfi ji,
Ara, ko to k’ awa ko ko
Lati ma f’ ija sile?
K’ a mu kuro
Ohun ‘ba mu ‘binu wa.
4. K’ a gb’ omonikeji wag a
Ju b’ a ba ti gbe ‘ra wa;
K’ a fi keta gbogbo sile,
K’ okan wa si kun fun ‘fe,
Yio row a
B’ a wa ni irepo l’ aiye.
(Visited 2,779 times, 1 visits today)