1. JESU, Iwo li a nwo,
K’ a repo l’ oruko Re;
Alade alafia,
Mu k’ ija tan larin wa.
2. Nipa ilaja tire,
Mu idugbolu kuro:
Jek’ a dapo si okan,
F itegun Re s’ arin wa.
3. Jek’ a wa ni okan kan,
K’ a se anu at’ ore;
K’ a tutu l’ero, l’ okan,
Gege bi Oluwa wa.
4. K’ a s’ aniyan ara wa,
K’ a ma r’ eru ara wa,
K’ a f’ apere fun ijo,
B’ olugbagbo ti gbe po.
5. K’ a kuro ni ibinu,
K’ asimi le Olorun;
K’ a so ti ibu ife,
At’ iwa giga mimo.
6. K’ a f’ ayo kuro l’ aiye
Lo si ijo ti orun;
K’ a f’ iye angeli fo,
K’ a le ku b’ eni mimo.
(Visited 1,009 times, 1 visits today)