1. WO! b’ o ti dun to lati ri
Awon ara t’ o re;
Ara ti okan won s’ okan,
L’ egbe ide mimo.
2. ‘Gba isan ‘fe t’ odo Krist’ sun,
O san s’ okan gbogbo;
‘Lafia Olodumare
Dabo bo gbogbo re.
3. O dabi ororo didun,
Ni irugbon Aaron’;
Kikan re m’ aso re run ‘ re,
O san s’ agbada re.
4. O dara b’ iri owuro
T’ o nse s’ oke Sion’,
Nibit’ Olorun f’ ogo han,
T’ O m’ ore-ofe han.
(Visited 370 times, 1 visits today)