1. IFE orun t’ o teriba
Lati pin ninu ekun wa:
Iwo l’ a k’ aniyan wa le,
Ko si nkan gbat’ O sunmo wa.
2. B’ ona ajo wa tile gun,
T’ ibanuje kun odun won;
A kio ya, be l’ a kio beru,
Okan wa nso p’ O sunmo wa.
3. Nigbat’ ayo d’ ibanuje,
Ti igbagbo si d’ ifoiya,
Afele at’ ewe ti nfe,
Nwon nso fun wa p’ O sunmo wa.
(Visited 277 times, 1 visits today)