1. NIHIN l’ ayida wa,
Ojo, erun nkoja;
Ile ni nyan, ti o si nsa,
‘Tana dada si nku;
Sugbon oro Jesu duro,
“Ngo wa pelu re” ni On wi.
2. Nihin l’ ayida wa;
L’ ona ajo orun;
Ninu ‘gbagbo, ‘reti at’ eru,
N’nu ‘fe s’ Olorun wa;
A nsaika oro yi sip o!
“Ngo wa pelu re” ni On wi.
3. Nihin l’ ayida wa;
Sugbon l’ arin eyi,
L’ arin ayidayid’ aiye,
Okan wa ti ki yi;
Oro Jehofa ki pada;
“Ngo wa pelu re” ni On wi.
4. Ona alafia,
Emmanueli wa,
Majemu ti ore-ofe;
Lai nwon ki yipada;
“Nki yipada,” l’ oro Baba,
“Ngo wa pelu re” ni On wi.
(Visited 221 times, 1 visits today)