YBH 330

A IGBAGBO bila! T’ emi l’ Oluwa

1. A IGBAGBO bila! T’ emi l’ Oluwa
On o si dide fun igbala mi;
Ki nsa ma gbagura, On o se ‘ranwo;
‘Gba Krist’ wa lodo mi, ifoiya ko si.

2. B’ ona mi bas u, On l’ O san to mi,
Ki nsa gboran sa, On o si pese;
B’ iranlowo eda gbogbo ba saki,
Oro t’ enu Re so y’o bori dandan.

3. Ife t’ o nfi han, ko je ki nro pe,
Y’o fi mi sile ninu wahala;
Iranwo ti mo si nri lojojumo,
O nki mi l’ aiya pe emi o la ja.

4. Emi o se kun tori iponju,
Tabi irora? O ti so tele!
Mo m’ oro Re p’ awon ajogun ‘gbala,
Nwon ko le sai koja larin wahala.

5. Eda ko le so kikoro ago
T’ Olugbala mu k’ elese le ye;
Aiye Re tile buru ju t’emi lo,
Jesu ha le jiya, k’ emi si ma sa.

6. Nje b’ ohun gbogbo ti nsise ire,
Adun n’ ikoro, onje li ogun;
B’ oni tile koro, sa ko nip e mo,
Gbana orin ‘segun yio ti dun to!

(Visited 1,269 times, 3 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you