1. SISE, akoko nlo,
Se tokantokan;
Sise, okan nsegbe,
Sise, oru mbo,
N’nu ogba Oluwa
Lo sise loni,
Ma duro laise nkan,
Mase jafara.
2. N’nu ‘pe t’ o l’ ogo yi,
Lo gbogbo ojo,
Sise titi oru
K’y’o je k’ o se mo,
Gbana ao gbe ‘se re
To Oba ogo,
Li apa angeli,
Pel’ orin ayo.
3. Nib’ awon mimo nsin,
T’ awon t’ a gba pe,
Ao gbe tire le ‘le,
Ni iwaju Re,
Gbo b’ Oluwa ti nwi
Lori ite Re,
Gbat’ a nsan ere re,
“O seun osise.
(Visited 503 times, 1 visits today)