1. OKAN wa ji; k’ eru fo lo,
Ki gbogbo ifoiya k’o lo;
Ji, k’ o sis are ‘je orun,
Si fi igboiya ayo han.
2. Loto, elegun l’ ona wa,
Eran ara si ma s’ are;
Sugbon nwon gbagbe Oluwa,
Ti nf’ agbara fun enia Re.
3. Oluwa, ipa Enit’ o
J’ otun at’ ewe titi lai,
T’ o si f’ idi mu ‘le titi,
At’ aiye d’ aiye yio ma lo.
4. Lat’ ara Re, Orisun nla
L’ okan wa y’o mu amuyo;
Gb’ awon t’ o gbekel’ ara won
Ba subu, tin won ba si ku.
5. Gege b’ idi ti yara fo,
Be l’ ao fo lo s’ ibugbe Re;
Emi wa yio si f’ ayo lo,
Laise are l’ ona orun.
Support Yoruba Baptist Hymns
Every week, thousands of believers use YorubaBaptistHymns.com to access Yoruba Baptist hymns for worship and ministry.
In the last 6 months alone, people searching for Yoruba Baptist hymns found this platform over 297,000 times on Google, with more than 48,000 visitors every month.
If this platform has blessed you or your church, consider helping sustain this hymn archive so it remains available for worshippers around the world.
Support the Hymn Archive