YBH 36

JESU, a fe pade

1. JESU, a fe pade,
L’ ojo Re mimo yi;
A si y’ ite Re ka,
L’ ojo Re mimo yi;
‘Wo Ore wa orun,
Adura w ambo wa,
Bojuwo emi wa
L’ ojo Re mimo yi.

2. A ko gbodo lora,
L’ ojo Re mimo yi;
Li eru a kunle
L’ ojo Re mimo yi;
Ma taro ise wa,
K’ Iwo k’ o si ko wa,
K’ a sin O b’ o ti ye
L’ ojo Re mimo yi.

3. A teti s’ oro Re,
L’ ojo Re mimo yi;
Bukun oro t’ a gbo,
L’ ojo Re mimo yi;
Ba wa lo ‘gbat’ a lo,
F’ ore igbala Re
Si aiya wa gbogbo,
L’ ojo Re mimo yi.

(Visited 9,487 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you