YBH 37

OSE, ose rere

1. OSE, ose rere,
Iwo ojo ‘simi;
O ye k’ a fi ojo kan,
Fun Olorun rere;
B’ ojo mi tile m’ ekun wa,
Iwo n’ oju wa nu;
Iwo ti s’ ojo ayo,
Emi fe dide re.

2. Ose, ose rere,
A k’yo sise loni;
A o f’ ise wa gbogbo
Fun aisimi ola,
Didan l’ oju re ma dan,
‘Wo arewa ojo;
Ojo mi nso ti lala,
Iwo nso t’ isimi.

3. Ose, ose rere,
Ago tile nwipe,
F’ Eleda re l’ ojo kan,
T’ O fun O ni mefa;
A o f’ ise wa sile,
Lati lo sin nibe,
Awa ati ore wa,
Ao los’ ile adua.

4. Ose, ose rere,
Wakati re wu mi;
Ojo orun n’ iwo se,
‘Wo apere orun,
Oluwa je ki njogun
‘Simi lehin iku,
Ki nle ma sin O titi,
Pelu enia Re.

(Visited 6,216 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you