1. OJO ‘mole l’ eyi,
K’ imole wa l’oni;
‘Wo, Orun, ran s’ okunkun wa,
K’o si le oru lo.
2. Ojo ‘simi l’eyi,
S’ agbara wa d’ otun;
S’ ori aibale aiya wa
Se ‘ri itura Re.
3. Ojo alafia,
F’ alafia fun wa;
Da iyapa gbogbo duro,
Si mu ija kuro.
4. Ojo adua ni
K’ aiye sunmo orun;
Gb’ okan wa s’ oke s’odo Re,
Si pade wa nhin.
5. Oba ojo l’ eyi,
Fun wa ni isoji;
Ji oku okan wa s’ife,
‘Wo asegun iku.
(Visited 774 times, 1 visits today)