1. EYI l’ ojo Oluwa da,
O pe ‘gba na n Tire;
K’ orun ko yo, k’ aiye k’ o yo,
K’ iyin y’ ite na ka.
2. Loni, O jinde n’nu oku,
Ijoba Satan’ tu;
‘Won mimo tan ‘segun Re ka,
Nwon ns’ oro ‘yanu Re.
3. Hosanna si Oba t’ a yin,
S’ Omo mimo Dafid’
Oluwa, jo sokale wa
T’ Iwo t’ igbala Re.
4. Abukun l’ Oluwa t’ O wa
N’ ise ore ofe;
T’ O wa l’ oruko Baba Re,
Lati gba ‘ran wa la.
5. Hosanna li ohun goro
L’enia Re le wi;
Orun giga nib’ O joba.
O f’ iyin giga fun.
(Visited 559 times, 1 visits today)