YBH 373

JESU t’ O wa gba mi la

1. JESU t’ O wa gba mi la,
Wo ‘nu odo Jordani,
O jade kuro n’nu re,
A si m’ O l’ Om’-Olorun,
Nipa ohun ‘fe Baba,
At’ iwa ‘le Adaba;
Jesu, Oluto t’emi,
Bi Re mo fe ‘tebomi.

2. Nin’ ogba, ibanuje
Bo okan Re bi omi;
Ni Kalfari, lor’ igi,
A! ni Jesu ku fun mi,
A kan mi po pelu Re,
‘Reti mi ni pe O ku;
Mo mu ‘po mi l’ese Re,
Mo njiya nitori Re.

3. N’nu ‘boji titun l’ O sun,
O mu eru re kuro,
O la ‘kuta re koja,
O l’ ogo titi lailai,
Mo fe k’ a sin mi mo Krist’,
Nin’ ase t’ a bere yi,
Bi mo si ti nyo s’ oke,
Ki nwa l’ otun s’ Olorun.

(Visited 314 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you