1. OLUWA, nje ‘dariji Re
Yio gb’ eni bi emi?
Nje, O gbe ese mi kuro
O f’ erin bukun mi?
2. Nje fun mi l’ O r’ agbelebu
Lai nani egan Re?
Jesu, o ha to ki ntiju
Bida O lo s’ odo?
3. O se ‘ra Re l’apere nla
Li odo Jordani?
Igberaga mi yio ha ko
Lati s’ ohun t’ O se?
4. Jesu, itara ife Re
Mba ilora mi wi;
Ese mi nisiyi si nrin
Li ona didun Re.
(Visited 202 times, 1 visits today)