1. OJO ayo l’ ojo ti mo
Yan O, ‘Wo Olugbala mi;
O to ki okan mi ko yo,
K’ o si s’ ayo re kakiri
Ojo nla l’ ojo na,
Ti Jesu we ese mi nu!
O ko mi kin ma gbadura,
Ki nma sora, ki nsi ma yo,
Ojo nla l’ ojo na
Ti Jesu we ese mi nu.
2. A ti pari ise nla na,
Emi t’ Oluwa, On t’ emi;
O fa mi, mo si tele O,
Mo yo lati gba ipe na,
3. Simi ais’ okan, okan mi,
Simi l’ ori ipinnu yi;
Mo r’ ipa t’ o l’ ola nibi,
Ayo orun kun mi l’ aiya,
4. Orun giga t’ o gb’ eje mi,
Yio gbo l’ otun l’ ojojumo,
Titi ngo fi f’ ibukun fun,
Idapo yi l’ oju iku.
(Visited 1,148 times, 1 visits today)