1. JESU ni, “Gb’ agbelebu re
Ki o si ma tele Mi,”
Oro yi ha le mu wag bon?
A o ha sa fun eru na?
Jesu ngo gbe,
Ngo si tele O l’ ayo..
2. Bi mo ti nwo ‘boji omi,
Apere t’ Oluwa mi,
Ngo ha ko bebe re, ki nfi
Iwa bi ti eru han?
Ngo wo ‘nu re;
Jesu wo ‘do Jordani.
3. Alabukun ni fun ami
T’ o mu mi niran ‘fe Re;
Sugbon ju ‘yi lo ni ife
T’ o f’ aiku de mi mo O;
Ayo nla ni
Lati sin mi pelu Re.
4. B’ eyi tile mumi pinya,
B’ o mu mi ri itiju,
Sibe adun iranti pe,
Mo ti de ‘biti O wo,
Yio m’ okun wa
Gb’ agbelebu npa mi lo.
5. Ninu ‘dapo pelu Jesu,
Jek’ ife mi ku s’ ese
Ki ndide lati gba ‘bukun
T’ awon t’ o gbagbo yio gba;
A! ti mba le
Ma tele Jesu titi.
(Visited 113 times, 1 visits today)