YBH 382

OLUWA orun at’ aiye

1. OLUWA orun at’ aiye!
Jesu, Omo ninu ara!
Emi Mimo fun ‘toju wa!
E gbo, ki E si gb’ eje wa.

2. A gba O, Jesu ti a pa,
A gba ‘Wo t’ O r’ oke orun;
Pelu Re a ti ku s’ ese,
Okan wa si nfe ba O ji.

3. A gba ihinrere Re gbo,
A nlo, owo Re yio to wa;
L’ odo Jordani a nw’ ona
T’ awon Tire gba d’ odo Re.

4. Nipa ‘tebomi – ami nla –
Awa fi ara wa fun O
F’ edidi te majemu na,
K’ O gba wa fun Tire lailai.

(Visited 355 times, 1 visits today)

Sign up for our Newsletter

We promise not to spam you