1. WO t’ O teriba nin’ odo Jordani,
T’ O mokun n’nu ‘banuje wa, t’ O si ku
T’ O jinde ninu okunkun sin’ ogo,
T’ O si gba ‘joba ife awon Tire.
2. Ona Re l’ a ntele si inu odo,
K’ a sin wa pelu Re ninu iku Re,
T’ a si ji l’ aworan Re k’ a le t’ ona
T’ o nfi gbogb’ agbara dan s’ ojo mole.
3. Jesu Olugbala, ‘Wo Oluwa wa,
Nipa ijiya at’ oro anu Re,
Gba wa la, ki O si ma gbe inu wa,
K’ O p’ okan wa mo kuro inu ese.
4. K’ a to gb’ ade ogo at’ imo lowo,
At’ aso ala t’ eje Jesu ti fo,
A dapo mo awon mimo t’ o ti lo,
Ninu ‘yanu, lati bukun O titi lai.
(Visited 127 times, 1 visits today)